ÌGBÀ NINÚ ỌDÚN ( seasons of the year)

Oríṣìíríṣìí ìgbà ló wà nínú ọdún, àwọn ìgbà ná̀à ni; ìgba ẹ̀ẹ̀rùn, ìgbà òòrùn, ìgbà  òjò, ìgbà ọ̀gìnnìtìn, àti ìgbà ọyẹ̀.

 

ÌGBÀ Ẹ̀Ẹ̀RÙN: Àsìkò ọ̀gbẹlẹ̀ tí òjò ti dáwọ́ dúró ni ìgbà ẹ̀ẹrùn. Ooru ḿaa ń mú gan an nitorí òórùn  máa ń ràn púpọ̀ ní àsìkò yìí.

 

ÌGBÀ OORU: Ìgbà ooru ni ìgbà tí ilẹ̀ gbẹ, tí òjò kò rọ̀  mọ̀. Àìsàn tábí àrùn máa ń pọ̀ ni ìgbà ooru. Awọ̀tẹ́lẹ̀ ni àwọn ènìyàn máa ń wọ̀ ní àsìkò yìí pàápàá jùlọ bí wọ́n bá wà nínú ilé.

IGBA OJO: oúnje máa ń pọ́ ni ìgbà òjò dáradára. Àmọ́ òtútù máà ń mú ni àsìkò yìí. Ẹni tó bá ní àìsàn rán- angun rán- angun máa ń ṣe àìsàn ní ìgbà òjò nítorí òtútù.

 

ÌGBÀ Ọ̀GÌNNÌTÌN: Èyi ni ìgbà tàbi àsìkò tí òjò máà ń rọ̀ léraléra ni àárin ọdún. Òtútù máa ǹ mú púpọ̀ ní àkókò ọ̀gìnnìtìn nítorí èyí, àwọn ènìyán máa ń wọ aṣọ tó nípọn dáadáa.

 

ÌGBÀ ỌYẸ́: Ìgbà ọyẹ́ ni àsikò tí òtútù máa ń mú nítorí afẹ́fẹ́ ọyẹ́ tó ń fẹ́. Ara àwọn ènìyàn máa ń funfun ní àsìkò yìí. Ètè àwọn ènìyàn máa ń lá ní àsìkò ọyẹ́. Ọyẹ́ ni ọkọ ooru.

 

School Owner? Automate operations, improve learning outcomes and increase your income with Afrilearn SMS

Get more class notes, videos, homework help, exam practice on Android [DOWNLOAD]

Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!