Back to: Yoruba Primary 2
Gbogbo ọjà tí àwọn Yorùbá ń tà ni wọ́n ní ìpólowó fún, diẹ̀ laŕa wọn nìwọ̀nyí;
| Ọjà | Ip̀olówó |
| Àgbàdo | Láńgbé jiná o |
| Ègbo | Yọ́rìí ègbo rè é |
| Ọ̀lẹlẹ̀ | Olúkanyọ̀, ó lépo, ó níyọ̀, mọ́ín-mọ́ín |
| Ìṣáná | Epo, ọ̀ọ̀lè. ròdò, Ẹ ra ìṣáná, ẹ má tọrọ lò |
| Epo pupa | Ẹ repo ẹ sẹbẹ̀ |
| Àkàrá | Làròdó rè é o, ẹ kengbe àkàá |
| Iṣu | Ó tú sépo múyẹ́, ọkọ mi ló ń gbìn in èmi ni mò ń tà á |
| Àmàlà | Àmàlà rè é, ẹran rè é |
| Èkuru | Ìbóǹbó èkuru rè é |
| Awùsá | Ó gbó keke bí obì, ó dùn bí oyin |
IṢẸ́ ṢIṢE
Àwọn ọjà won ni à ń polówó báyìí?
- Láńgbé jiná o
- Olúkanyọ̀, ó lépo, ó níyọ̀, mọ́ín mọ́ín epo
- Ẹ repo ẹ ṣebẹ̀
- O tú sépo múyé, ọkọ mi ḷó ń gbìn ín èmi ni mó ń tà á.