Back to: Yoruba Primary 2
Apàlọ́: Ààlo o
Agbálọ̀ọ́: ààlọ̀
Apàlọ́: Àlọ́ ni dá lórí Ìjàpà, Yánníbo ati babálawo.
Ọ̣kọ àti Ìyàwó ni Ìjápá ati Yánníbo
Wọn kò rí ọmọ bí.
Ìjàpá wá lọ sí ọ̀dọ́ babaláwo fún ọ̀nà àbáyọ.
Babaláwo ṣe àṣèjẹ, ó si gbé e fún ìjàpá pé kò rí í pé Yánnibo jẹ ẹ́ tán.
Babaláwo kilọ̀ fún Ìjápá pé kò gbódọ̀ jẹ́ nínú ọbẹ́ àṣèjẹ náà.
Ṣùgbọ́n nigbà tí ìjàpá dé ojú ọ̀nà, ó kó gbogbo ọbẹ̀ àsèjẹ náa jẹ.
Láì pẹ́, ikùn ìjàpá bẹ̀rẹ̀ ṣí ní yọ bí í tí olóyún.
Ijàpá bá ń kọrin láti bẹ babaláwo báyìí;
Apálọ́: babaláwo mo wá bẹ̀bẹ̀
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: babaláwo mo wá bẹ̀bẹ̀
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: Ó ni n má mà fọwọ́ bọnu
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: O ni n má mà fẹsẹ̀ bọnu
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: Gbòǹgbò ló yọ ọ̀ mí gẹ̀rẹ̀
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: Mo tọwọ́ bọbẹ̀, mo fi bọnu
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: Mo bojú wokùn ó rí gbẹndu
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Apálọ́: babaláwo mo wá bẹ̀bẹ̀
Agbálọ̀ọ́: Alugbinrin
Babaláwo sọ́ fún ìjàpá pé kò sí àtúnṣe mọ́, báyìí ni ìjàpá wú títí ó fi bẹ.
IṢẸ́ ṢIṢE
Sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí àlọ́ “ÌJÀPÁ, YÁNNÍBO ÀTI BABALÁWO kọ́ ẹ.
(write lessons you learnt from folktales of tortoise, his wife and the herbalist)
School Owner? Looking for ready-made content and tools to save time and grow easily? Book a free demo session nowGet more class notes, videos, homework help, exam practice on Android [DOWNLOAD]
Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]
Good