ÀRÒFỌ̀ AKỌ́NILỌ́GBỌ́N KÉÉKÈÈKÉ  III (moral poem III) -EKO

Ẹ̀KỌ́ (EDUCATION)

Oríṣìíriṣìí ẹ̀kọ́ tá a kọ́

La fi ń gbáyé nídẹ̀ra

Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tá a ní

Ló jẹ́ kí a mọ bá a ṣe mọ

Ẹ̀kọ́- ilé dúró gédégbé

Ó ṣe kókó, ọ́ pọ̣n dandan

Ṣ̣ebí ọ̣mọ̣ tí òbí bí tí kò kọ́

Ló ń gbélé tà ní wàràwàrà

Ẹ̀kọ́ ìwé tó gbòde kan ńkọ́?

Òhun ló kúkú tànmọ́lẹ̀

Sóhun tọ́ ṣókùnkùn si mùtúmùwà

̣Ọmọ aráyẹ́ ẹ gbọ́, ẹ jẹ́ ká tẹra mọ́ ọn

Káyé wa le dùn ní yùngbà yùngbà

Bó sì ṣeṣẹ́ lo fẹ́ kọ́

Rọ́jú kọ́ ọ kó yanjú dáadáa

Akọ́sẹ́ yege ló le dúró láwùjọ ènìyàn pàtàkì.

Are you a Parent? Share your quick opinion and win free 2-month Premium Subscription

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!