ÀRÒFỌ̀ AKỌ́NILỌ́GBỌ́N KÉÈKÈÈKÉ I ( moral poem I)

ÌWÀ (Attitude)

Ìwà ṣe pàtàkì

Ó ṣe kókó

Òhun la fi ń dẹni gíga

Bá a bá délùú tá à ti lárá

Bá a débi tá à ti lénìyàn

Ìwà ló yẹ kání

Ẹ jẹ́ kó máa ye gbogbo wa

Ìwà ti ṣo ènìyàn dẹni táyé ń wárí fún rí

O ti sọ ọ̀pọ̀ dẹni ìgbà ń dùn fún yùngbà

Ìwá tí à ń sọ nìpa rẹ̀ yìí́

Ti sọ ẹlòmíràn dẹni yẹpẹrẹ lágbo ilé wọn

Ìwà rere mọ ṣebi ́òhun lẹ̀sọ́ ènìyàn

Báwo nìwà rẹ ṣe ri láàrin ẹgbẹ̀?

Ki ni wọ́n ń ṣọ nipa tiyín níbiṣẹ́ ọba?

Tun wà rẹ ṣe ọ̀rẹ, káyé le yé ọ́

Kó tún yẹ gbogbo ẹni tí ń bá ọ jórúkó.

 

Get more class notes, videos, homework help, exam practice on Android [DOWNLOAD]

Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!