Back to: Yoruba Primary 2
Oríṣìíríṣìí ìgbà ló wà nínú ọdún, àwọn ìgbà ná̀à ni; ìgba ẹ̀ẹ̀rùn, ìgbà òòrùn, ìgbà òjò, ìgbà ọ̀gìnnìtìn, àti ìgbà ọyẹ̀.
ÌGBÀ Ẹ̀Ẹ̀RÙN: Àsìkò ọ̀gbẹlẹ̀ tí òjò ti dáwọ́ dúró ni ìgbà ẹ̀ẹrùn. Ooru ḿaa ń mú gan an nitorí òórùn máa ń ràn púpọ̀ ní àsìkò yìí.
ÌGBÀ OORU: Ìgbà ooru ni ìgbà tí ilẹ̀ gbẹ, tí òjò kò rọ̀ mọ̀. Àìsàn tábí àrùn máa ń pọ̀ ni ìgbà ooru. Awọ̀tẹ́lẹ̀ ni àwọn ènìyàn máa ń wọ̀ ní àsìkò yìí pàápàá jùlọ bí wọ́n bá wà nínú ilé.
IGBA OJO: oúnje máa ń pọ́ ni ìgbà òjò dáradára. Àmọ́ òtútù máà ń mú ni àsìkò yìí. Ẹni tó bá ní àìsàn rán- angun rán- angun máa ń ṣe àìsàn ní ìgbà òjò nítorí òtútù.
ÌGBÀ Ọ̀GÌNNÌTÌN: Èyi ni ìgbà tàbi àsìkò tí òjò máà ń rọ̀ léraléra ni àárin ọdún. Òtútù máa ǹ mú púpọ̀ ní àkókò ọ̀gìnnìtìn nítorí èyí, àwọn ènìyán máa ń wọ aṣọ tó nípọn dáadáa.
ÌGBÀ ỌYẸ́: Ìgbà ọyẹ́ ni àsikò tí òtútù máa ń mú nítorí afẹ́fẹ́ ọyẹ́ tó ń fẹ́. Ara àwọn ènìyàn máa ń funfun ní àsìkò yìí. Ètè àwọn ènìyàn máa ń lá ní àsìkò ọyẹ́. Ọyẹ́ ni ọkọ ooru.
Get more class notes, videos, homework help, exam practice on Android [DOWNLOAD]
Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]