Back to: Yoruba Primary 2
Gbogbo ọjà tí àwọn Yorùbá ń tà ni wọ́n ní ìpólowó fún, diẹ̀ laŕa wọn nìwọ̀nyí;
Ọjà | Ip̀olówó |
Àgbàdo | Láńgbé jiná o |
Ègbo | Yọ́rìí ègbo rè é |
Ọ̀lẹlẹ̀ | Olúkanyọ̀, ó lépo, ó níyọ̀, mọ́ín-mọ́ín |
Ìṣáná | Epo, ọ̀ọ̀lè. ròdò, Ẹ ra ìṣáná, ẹ má tọrọ lò |
Epo pupa | Ẹ repo ẹ sẹbẹ̀ |
Àkàrá | Làròdó rè é o, ẹ kengbe àkàá |
Iṣu | Ó tú sépo múyẹ́, ọkọ mi ló ń gbìn in èmi ni mò ń tà á |
Àmàlà | Àmàlà rè é, ẹran rè é |
Èkuru | Ìbóǹbó èkuru rè é |
Awùsá | Ó gbó keke bí obì, ó dùn bí oyin |
IṢẸ́ ṢIṢE
Àwọn ọjà won ni à ń polówó báyìí?
- Láńgbé jiná o
- Olúkanyọ̀, ó lépo, ó níyọ̀, mọ́ín mọ́ín epo
- Ẹ repo ẹ ṣebẹ̀
- O tú sépo múyé, ọkọ mi ḷó ń gbìn ín èmi ni mó ń tà á.
Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]