ÀRÒFỌ̀ AKỌ́NILỌ́GBỌ́N KÉÉKÈÈKÉ II ( moral poem II) – ISE

IṢẸ̀ (WORK)

Iṣ̣ẹ̣́ mo ṣe bi òhun lòògùn ìṣ̣ẹ

Iṣ̣ẹ́ a máa sọni dẹni ńlá

Iṣ̣ẹ́ a tùn máa sọni dẹni gíga

Iṣ̣ẹ́ lòsùpá ń ṣe lóju ọ̀run lọ́hùn- ún

Iṣ̣ẹ́ lòòòrun ń sẹ ní sánmọ̀ tó wá.

Ọ̀pọ̀ ló ti dẹni ti ń tọ̣rọ jẹ

Látàrí àìníṣẹ́ lápá

Wọ́n dẹni ń bẹ̀bẹ̀ kiri

Kí wọ́n tó le róhun fètè kàn

Bi iṣẹ́ rẹ lónii kó bá mérè tó pọ̀ wá

Rọ́jú kó o tẹ̣ra mọ́ ọn gidi gan an

Ó le mówó tó jọjú wọ́lé bó dọ̀la

Kò sẹ́ni tí kò lé dára fún láyé

Àfi bó bá jẹ́ ọ̀lẹ ìlú ló kù

Kò sóhun méjì tó káwọ́ ìṣẹ́

Tó ju ká ṣiṣẹ́ lọ ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi

O ò bá ṣàgbẹ́

Bó o sì jákọ̀wé

Iṣẹ̣́ ẹni níí lani

Kódà bó ṣe wóróbo lo rí dáwọ́lé

Bó sì ṣẹrù lò ń gbàrù l’óyìngbọ̀

Dákun múra sí i láì ṣàárẹ̀

Iṣẹ́ lèrè ẹ̀dá láyé.

Your Opinion Matters! Quickly tell us how to improve your Learning Experience HERE

Pass WAEC, JAMB, NECO, BECE In One Sitting CLICK HERE!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!