Ẹ́RE ÌDÁRAYÁ: ẸYẸ MẸ́TA TOLONGO WÁYÉ (games)

Ẹyẹ mẹ́ta tolongo wáyé

Àwọn ọmọdé yóò kó ara wọn jọ, wọn yóò yan ẹnikan tí yó̀ò jẹ́ aládarí wọn. Aládarí yìí yóò dúró sí ẹ̀yìn nígbá tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yóò wà níwájú tàbí kí wọ́n wà lẹ́yìn kí òun sì wà ní iwájú. Aládarí yìí yóò máa lé orin ti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yóò máa gbè é bí wọ́n ṣe ń rìn yí po ààrin kan.

Lílé: Ẹyẹ mẹ́ta tolongo wáyé

Ègbè: Tolongo

Lílé:: Ọ̀kan dúdú aró

Ègbè: Tolongo

Lílé:: Ọ̀kan rẹ̀rẹ̀ osùn

Ègbè: Tolongo

Lílé: Ṣó ṣò ṣó fìrú balẹ̀

Ègbè: Ṣó ò

Lílé: Ṣó ṣò ṣó fìrú balẹ̀

Ègbè: Ṣó ò

Lílé: Ṣó ṣò ṣó fìrú balẹ̀

Ègbè: Ṣó ò

 

Bí wọ́n bá ti dé ibi “Ṣó ṣò ṣó fìrú balẹ̀” tó gbẹ̀yìn ni gbogbo àwọn tó tẹ̀lé aládari yóò bẹ̀rẹ̀ mọ̀lẹ̀ tí wọn yóò sì dúró lórí ọmọ ika ọwo ati tẹsẹ̀ wọn ti wọn yóò sì máa wolẹ̀. Bí aládarì bá wo ẹ̀yin lójiji tó bạ́ sì ri ẹnikẹ́ni tí kò wolẹ̀ tàbí dúró lórí ọmo ika ọwọ́ ati tẹsẹ̀ rẹ̀, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ yóò kúrò nínú eré náà.

Báyìí ni wọn yòó máa bá eré yìí bọ̀ títí yóò fi ku ẹnikan ṣoṣo lẹ́yin aládarí. Ẹni yìí ni yóò si gba ògo eré náá. Ìdi tí wọ́n fi ń dúró lórí ọmọ ìka ọwọ́ ati tẹsẹ̀ wọ́n ni kí ó bà le gbó dáradára.̣

For more class notes, homework help, exam practice, download our App HERE

Join ClassNotes.ng Telegram Community for exclusive content and support HERE

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!