Ẹ̀kọ́ Ìdárayá: Bojúbojú (games)

Eré ìdárayá ni bojúbojú jẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá. Àwọ̣n ọ̣mọdé ló ń ṣe é, kò sí fún àgbàlagbá rárá. Ọ̣mọdé bí i mẹ́fà sí mẹ́jọ lè kópa nínú eré bojúbojú lẹ́ẹ̀kan náà.

 

Àwọn tó fẹ́ ṣe erè yìí yóò yan ẹnikan ti yóò bo ẹlòmiràn lójú. Ó lè fi aṣọ tàbí ọwọ́ dì í tàbí bò ó lójú. Kété tó bá di ojú ẹni yìí ni àwọn yòókù yóò ti lọ fi ara pamọ́ si ibìkan. Ẹni tó di ẹlòmíràn lójú yìí yóò máa lé orin nígbà tí àwọn yòókù tó ti fara pamọ́ tàbí tó sì ń sáré kiri látí fara pamọ́ yóò máa gbe orin náà báyìí:

Lílé: bojúbojú

Ègbè: oo

Lílé: Olórò ń bọ̀

Ègbè: oo

Lílé: Ẹ para mọ́ o

Ègbè: oo

Lílé: Ṣé ki n ṣi

Ègbè: Ṣi

Lílé: Ṣi ṣi ṣi ṣi

Ègbè: ṣi

Lílé: Ẹni tólórò bá mú á pa á jẹ

Ègbè: Pa á jẹ.

 

Kété tí gbogbo wọn bá ti fara pamọ́ tán ni wọn yóò sọ fún ẹni tó bo olórò lójú pé kó si i sílẹ̀. Yóò si bẹ̀rẹ̀ sí ní wá wọn kiri. Bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ọ̀kan nínú wọn, onítọ̀ún ni yóò di olórò tị́ yóò maa wá àwọn yòóku kiri.

Bí ilẹ̀ bá ṣe ń ṣú sí ni eré yìí máa ń dùn sí. Ìdí rẹ̀ ni pé ẹni tó jẹ́ olórò kò ní fẹ́ kí eré náà ó parí sórí òun lá̀ì jẹ́ pé ọ̣wọ òun náà kan ẹnikan tí yóò rọ́ pò òun. Bí àwọn tó ń ṣe eré yìí kó bá sọ́ra, wọ́n lè fara pa níbí tí wọ́n tí ń sáré kiri láti fara pamọ́ fún olórò.

School Owner? Looking for ready-made content and tools to save time and grow easily? Book a free demo session now

Get more class notes, videos, homework help, exam practice on Android [DOWNLOAD]

Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]

1 thought on “ Ẹ̀kọ́ Ìdárayá: Bojúbojú (games)”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!