Back to: Yoruba Primary 1
Àlọ́ àpamọ̀ ni irúfẹ́ àlọ́ tó jẹmọ́ ibéèrè àti ìdáhùn, àlọ́ yìí kìí ní orín nínu rárá, ó máa ń fúnmi ní ànfàání látí ronú jínlẹ̀. Ẹni tí ó ń pa ạ̀lọ́ ni apàlọ́, nígbà tí àwọn ti à ń pa àlọ́ fún jẹ́ ajálọ̀ọ́
Àpẹẹrẹ Àlọ́ àpamọ̀ nìwọ̀nyí:
Apàlọ̀ọ́: Ààlọ́ o
Ajálọ̀ọ́: Ààlọ́
Apàlọ̀ọ́: Òkun ń hó ye, ọ̀sà ń hó ye, ọmọburúkú torí bọ̀ ọ́.
Ajálọ̀ọ́: ọmọrogùn (orógùn)
Apàlọ̀ọ́: Ọ̀pá tín- ín- rín kanlẹ̀ ó kànrun
Ajaloo: Òjò
Apàlọ̀ọ́: Ki ló bọ́ sómi tí kò ró tómú?
Ajálọ̀ọ́: Abẹ́rẹ́ (okinni)
Apàlọ̀ọ́: Kí ló ń kan ọba níkòó?
Ajálọ̀ọ́: Abẹ
Apàlọ̀ọ́: Ewéko abẹ́ ìrókò ajóni má fara hanni
Ajálọ̀ọ́: Wèrèpè
Apàlọ̀ọ́: Gbogbo ilé sùn lámọrín kò sùn
Ajálọ̀ọ́: Imú
Apàlọ̀ọ́: Ki ló kọjá lójúdé ọba tí kò kí ọba?
Ajálọ̀ọ́: Àgbàrá òjò
Apàlọ̀ọ́: Mo dúrọ́ ọwọ mi kó to, mo bẹ̀rẹ̀ ọwọ́ mi jù ú lọ
Ajálọ̀ọ́: Ọrúnkún
Apàlọ̀ọ́: Aṣọ baba mi kan láéláé, aṣọ baba kan làèlàè, etí ni ti ń gbó kìí gbó láàrin
Ajálọ̀ọ́: Odò
IṢẸ́ ṢÍṢE
Já àlọ́ wọ̀nyi: (complete the following folktales)
- Ọ̀pá tín-ín-rín kanlẹ̀ ò kànrun (Iná, Òjò)
- Kí ló bọ́ sómi tí kò ró tómú? (Abẹ́rẹ́, iṣó)
- Kí ló ń kan ọba níkòó? ( Àdá, Abẹ)
- Ewéko abẹ́ ìrókò ajóni má fara hanmi (Wèrèpè, ewé)
- Gbogbo ilé sùn lámọrín kò sùn (Imú, olé)
Get more class notes, videos, homework help, exam practice on Android [DOWNLOAD]
Get more class notes, videos, homework help, exam practice on iPhone [DOWNLOAD]