ÀLỌ́ ÀPAMỌ́ ( Folk tale)

Àlọ́ àpamọ̀ ni irúfẹ́ àlọ́ tó jẹmọ́ ibéèrè àti ìdáhùn, àlọ́ yìí kìí ní orín nínu rárá, ó máa ń fúnmi ní ànfàání látí ronú jínlẹ̀. Ẹni tí ó ń pa ạ̀lọ́ ni apàlọ́, nígbà tí àwọn ti à ń pa àlọ́ fún jẹ́ ajálọ̀ọ́

Àpẹẹrẹ  Àlọ́ àpamọ̀ nìwọ̀nyí:

Apàlọ̀ọ́: Ààlọ́ o

Ajálọ̀ọ́: Ààlọ́

Apàlọ̀ọ́: Òkun ń hó ye, ọ̀sà ń hó ye, ọmọburúkú torí bọ̀ ọ́.

Ajálọ̀ọ́: ọmọrogùn (orógùn)

Apàlọ̀ọ́: Ọ̀pá tín- ín- rín kanlẹ̀ ó kànrun

Ajaloo: Òjò

Apàlọ̀ọ́: Ki ló bọ́ sómi tí kò ró tómú?

Ajálọ̀ọ́: Abẹ́rẹ́ (okinni)

Apàlọ̀ọ́: Kí ló ń kan ọba níkòó?

Ajálọ̀ọ́: Abẹ

Apàlọ̀ọ́: Ewéko abẹ́ ìrókò ajóni má fara hanni

Ajálọ̀ọ́: Wèrèpè

Apàlọ̀ọ́: Gbogbo ilé sùn lámọrín kò sùn

Ajálọ̀ọ́:  Imú

Apàlọ̀ọ́: Ki ló kọjá lójúdé ọba tí kò kí ọba?

Ajálọ̀ọ́: Àgbàrá òjò

Apàlọ̀ọ́: Mo dúrọ́ ọwọ mi kó to, mo bẹ̀rẹ̀ ọwọ́ mi jù ú lọ

Ajálọ̀ọ́: Ọrúnkún

Apàlọ̀ọ́: Aṣọ baba mi kan láéláé, aṣọ baba kan làèlàè, etí ni ti ń gbó kìí gbó láàrin

Ajálọ̀ọ́: Odò

 

IṢẸ́ ṢÍṢE

Já àlọ́ wọ̀nyi: (complete the following folktales)

  1. Ọ̀pá tín-ín-rín kanlẹ̀ ò kànrun (Iná, Òjò)
  2. Kí ló bọ́ sómi tí kò ró tómú? (Abẹ́rẹ́, iṣó)
  3. Kí ló ń kan ọba níkòó? ( Àdá, Abẹ)
  4. Ewéko abẹ́ ìrókò ajóni má fara hanmi (Wèrèpè, ewé)
  5. Gbogbo ilé sùn lámọrín kò sùn (Imú, olé)
Your Opinion Matters! Quickly tell us how to improve your Learning Experience HERE

Pass WAEC, JAMB, NECO, BECE In One Sitting CLICK HERE!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!