ÀLỌ́ ONÍTAN ( folktale) – ÀLỌ́ ÌJÀPÁ, Ọ̀KẸ́RẸ́ ÀTI ASIN

Àlọ́ onítàn ni irúfẹ́ àlọ́ tó ni ìhun ìtàn tó lè dá lé èniyàn, ẹranko tàbí ohun mìíràn tí kò tilẹ̀ lẹ́mìí. Àlọ́ onítàn lè ní orin tàbí kí ó má ní. Irúfẹ́ àlọ́ yìí máa ń kọ́ni ní oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́. Àpẹ̀ẹrẹ àlọ́ onítàn tó ní orin nínú ni ÀLỌ́ ÌJÀPÁ, ỌKẸ́RẸ́ ATI ASÍN.

 

Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Ìjàpá.

Àwo ni wọ́n jọ ń tà.

Àwo ni Asín náà ń ta.

Ìsọ̀ àwo Asín àti Ọ̀kẹ́rẹ́ ló súnmọ́ ara wọn.

Ní ọjọ́ kan, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin Asín àti Ọ̀kẹ́rẹ́

Ìjàpá fẹ́ la ìjà sùgbọ́n ó ń gbìja

Ọkẹ́rẹ́ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Asín fi Ọ̀kẹ́rẹ́ śilẹ̀, ó bá gé Ìjàpá ní imú jẹ.

Ìjàpá bá pe àwọn èrò ọjà pé kí wọ́n gba òun lọ́wọ́ Asín, Ó bá ń kọrin báyìí pé:

 

Lílé: Asín òun ọ̀kẹ́rẹ́

Ègbè: Jó ó mi jó

Lílé: Àwọn ló jọ ń jà

Ègbè: Jó ò mi jó

Lílé: Ìjà yìí mo wá là

Ègbè: jó ó mi jó

Lílé: Asin bù ,mí nímú jẹ

Ègbè: Jó ó mi jó

Lílé: Ẹ gbà mí lọ́wọ́ rẹ̀

Ègbè: Jó ó mi jó

Lílé: Àwo mi ń bẹ lọ́jà

Ègbè: Jó ó mi jó

 

Àwọn èrò ọjà kò dá ìjàpá lóhùn títí Asín fi gé imú rẹ̀ jábọ́ sílẹ̀. Ìdí nìyí tí i mú ìjàpá fi rẹ́ mọ́lẹ̀ títí di òní olónìí.

Your Opinion Matters! Quickly tell us how to improve your Learning Experience HERE

Pass WAEC, JAMB, NECO, BECE In One Sitting CLICK HERE!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Don`t copy text!